Luku 15:3-7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, 4 (A)“Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i? 5 Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. 6 Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’ 7 (B)Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.
Read full chapter
Luku 19:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.