Add parallel Print Page Options

Pínpín ilẹ̀ tí ó kù

18 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.

Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín? Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojú wo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá. Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”

Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.” Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo.

10 Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

Ìpín ti ẹ̀yà Benjamini

11 Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Benjamini, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà Juda àti Josẹfu:

12 Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jordani, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jeriko ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù Beti-Afeni. 13 Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi, (èyí ni Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni

14 Láti òkè tí ó kọjú sí Beti-Horoni ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Baali (tí í ṣe Kiriati-Jearimu), ìlú àwọn ènìyàn Juda. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

15 Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa. 16 Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá Àfonífojì Refaimu O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli. 17 Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni. 18 Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Araba, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. 19 Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Beti-Hogla, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò Jordani ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù.

20 Odò Jordani sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn.

Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sààmì sí ìní àwọn ìdílé Benjamini ní gbogbo àwọn àyíká wọn.

21 Ẹ̀yà Benjamini ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí:

Jeriko, Beti-Hogla, Emeki-Keṣiṣi, 22 Beti-Araba, Ṣemaraimu, Beteli, 23 Affimu, Para, Ofira 24 Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

25 Gibeoni, Rama, Beeroti, 26 Mispa, Kefira, Mosa, 27 Rekemu, Irpeeli, Tarala, 28 Ṣela, Haelefi, ìlú Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu), Gibeah àti Kiriati, àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn.

Èyí ni ìní Benjamini fún ìdílé rẹ̀.

Division of the Rest of the Land

18 The whole assembly of the Israelites gathered at Shiloh(A) and set up the tent of meeting(B) there. The country was brought under their control, but there were still seven Israelite tribes who had not yet received their inheritance.

So Joshua said to the Israelites: “How long will you wait before you begin to take possession of the land that the Lord, the God of your ancestors, has given you? Appoint three men from each tribe. I will send them out to make a survey of the land and to write a description of it,(C) according to the inheritance of each.(D) Then they will return to me. You are to divide the land into seven parts. Judah is to remain in its territory on the south(E) and the tribes of Joseph in their territory on the north.(F) After you have written descriptions of the seven parts of the land, bring them here to me and I will cast lots(G) for you in the presence of the Lord our God. The Levites, however, do not get a portion among you, because the priestly service of the Lord is their inheritance.(H) And Gad, Reuben and the half-tribe of Manasseh have already received their inheritance on the east side of the Jordan. Moses the servant of the Lord gave it to them.(I)

As the men started on their way to map out the land, Joshua instructed them, “Go and make a survey of the land and write a description of it.(J) Then return to me, and I will cast lots for you here at Shiloh(K) in the presence of the Lord.” So the men left and went through the land. They wrote its description on a scroll, town by town, in seven parts, and returned to Joshua in the camp at Shiloh. 10 Joshua then cast lots(L) for them in Shiloh in the presence(M) of the Lord, and there he distributed the land to the Israelites according to their tribal divisions.(N)

Allotment for Benjamin

11 The first lot came up for the tribe of Benjamin according to its clans. Their allotted territory lay between the tribes of Judah and Joseph:

12 On the north side their boundary began at the Jordan, passed the northern slope of Jericho and headed west into the hill country, coming out at the wilderness(O) of Beth Aven.(P) 13 From there it crossed to the south slope of Luz(Q) (that is, Bethel(R)) and went down to Ataroth Addar(S) on the hill south of Lower Beth Horon.

14 From the hill facing Beth Horon(T) on the south the boundary turned south along the western side and came out at Kiriath Baal (that is, Kiriath Jearim),(U) a town of the people of Judah. This was the western side.

15 The southern side began at the outskirts of Kiriath Jearim on the west, and the boundary came out at the spring of the waters of Nephtoah.(V) 16 The boundary went down to the foot of the hill facing the Valley of Ben Hinnom, north of the Valley of Rephaim.(W) It continued down the Hinnom Valley(X) along the southern slope of the Jebusite city and so to En Rogel.(Y) 17 It then curved north, went to En Shemesh, continued to Geliloth,(Z) which faces the Pass of Adummim,(AA) and ran down to the Stone of Bohan(AB) son of Reuben. 18 It continued to the northern slope of Beth Arabah[a](AC) and on down into the Arabah.(AD) 19 It then went to the northern slope of Beth Hoglah(AE) and came out at the northern bay of the Dead Sea,(AF) at the mouth of the Jordan in the south. This was the southern boundary.

20 The Jordan formed the boundary on the eastern side.

These were the boundaries that marked out the inheritance of the clans of Benjamin on all sides.(AG)

21 The tribe of Benjamin, according to its clans, had the following towns:

Jericho, Beth Hoglah,(AH) Emek Keziz, 22 Beth Arabah,(AI) Zemaraim,(AJ) Bethel,(AK) 23 Avvim,(AL) Parah, Ophrah,(AM) 24 Kephar Ammoni, Ophni and Geba(AN)—twelve towns and their villages.

25 Gibeon,(AO) Ramah,(AP) Beeroth,(AQ) 26 Mizpah,(AR) Kephirah,(AS) Mozah, 27 Rekem, Irpeel, Taralah, 28 Zelah,(AT) Haeleph, the Jebusite city(AU) (that is, Jerusalem(AV)), Gibeah(AW) and Kiriath—fourteen towns and their villages.(AX)

This was the inheritance of Benjamin for its clans.(AY)

Footnotes

  1. Joshua 18:18 Septuagint; Hebrew slope facing the Arabah